Àwọn Ọba Keji 2:11-13 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Bí wọ́n ti ń lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́-ogun iná ati ẹṣin iná gba ààrin wọn kọjá, Elija sì bá ààjà gòkè lọ sí ọ̀run.

12. Bí Eliṣa ti rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó kígbe pe Elija, ó ní, “Baba mi, baba mi, kẹ̀kẹ́-ogun Israẹli ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.” Kò rí Elija mọ́, ó bá fa aṣọ rẹ̀ ya sí meji láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.

13. Lẹ́yìn náà ó mú aṣọ àwọ̀lékè Elija tí ó bọ́ sílẹ̀, ó sì pada lọ dúró ní etí odò Jọdani.

Àwọn Ọba Keji 2