Àwọn Ọba Keji 13:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún kẹtalelogun tí Joaṣi, ọmọ Ahasaya, jọba ní Juda ni Jehoahasi, ọmọ Jehu, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó jọba fún ọdún mẹtadinlogun.

2. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ náà sílẹ̀.

3. OLUWA bínú sí Israẹli, ó sì jẹ́ kí Hasaeli, ọba Siria, ati Benhadadi ọmọ rẹ̀ ṣẹgun Israẹli ní ọpọlọpọ ìgbà.

4. Nígbà tí Jehoahasi gbadura sí OLUWA, tí OLUWA sì rí ìyà tí Hasaeli fi ń jẹ àwọn eniyan Israẹli, ó gbọ́ adura rẹ̀.

Àwọn Ọba Keji 13