Àwọn Ọba Keji 12:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún keje tí Jehu jọba ní Israẹli ni Joaṣi jọba ní ilẹ̀ Juda, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ogoji ọdún. Sibaya tí ó wá láti ìlú Beeriṣeba ni ìyá rẹ̀.

2. Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA nítorí pé Jehoiada alufaa ń tọ́ ọ sọ́nà.

3. Ṣugbọn kò ba àwọn pẹpẹ ìrúbọ jẹ́, àwọn eniyan ń rú ẹbọ níbẹ̀, wọ́n sì ń jó turari.

Àwọn Ọba Keji 12