Amosi 9:10-13 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Gbogbo àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi ni ogun yóo pa, gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Ibi kankan kò ní bá wa!’

11. “Ní ọjọ́ náà, n óo gbé àgọ́ Dafidi tí ó ti wó ró. N óo tún odi rẹ̀ mọ, n óo tún un kọ́ yóo sì rí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí.

12. Àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun àwọn tí wọ́n kù ní Edomu, ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí à ń fi orúkọ mi pè. Èmi OLUWA, tí n óo ṣe bí mo ti wí, èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

13. “Ọjọ́ ń bọ̀, tí ọkà yóo so jìnwìnnì,tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè kórè rẹ̀ tánkí àkókò gbígbin ọkà mìíràn tó dé.Ọgbà àjàrà yóo so,tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè fi ṣe waini tánkí àkókò ati gbin òmíràn tó dé.Ọtí waini dídùn yóo máa kán sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá,ọtí waini yóo sì máa ṣàn jáde lára àwọn òkè kéékèèké.

Amosi 9