Amosi 2:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ run.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

4. Ó ní: “Àwọn ará Juda ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n ti kọ òfin èmi OLUWA sílẹ̀, wọn kò sì rìn ní ìlànà mi. Àwọn oriṣa irọ́ tí àwọn baba wọn ń bọ, ti ṣì wọ́n lọ́nà.

5. Nítorí náà, n óo sọ iná sí Juda, yóo sì jó àwọn ibi ààbò Jerusalẹmu ní àjórun.”

6. OLUWA ní: “Àwọn ará Israẹli ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí pé wọ́n ta olódodo nítorí fadaka, wọ́n sì ta aláìní nítorí bàtà ẹsẹ̀ meji.

7. Wọ́n rẹ́ àwọn talaka jẹ, wọ́n sì yí ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ po. Baba ati ọmọ ń bá ẹrubinrin kanṣoṣo lòpọ̀, wọ́n sì ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.

8. Wọ́n sùn káàkiri yí pẹpẹ inú ilé Ọlọrun wọn ká, lórí aṣọ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn onígbèsè wọn; wọ́n ń mu ọtí tí àwọn kan fi san owó ìtanràn.

Amosi 2