Aisaya 60:13-17 BIBELI MIMỌ (BM)

13. “Ògo Lẹbanoni yóo wá sí ọ̀dọ̀ rẹ:igi sipirẹsi, igi firi, ati igi pine;láti bukun ẹwà ilé mímọ́ mi,n óo sì ṣe ibi ìtìsẹ̀ mi lógo.

14. Àwọn ọmọ àwọn tí ń ni ọ́ lára yóo wá,wọn óo tẹríba fún ọ;gbogbo àwọn tí ń kẹ́gàn rẹ,yóo wá tẹríba lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ;wọn óo pè ọ́ ní ìlú OLÚWA,Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

15. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ̀ ọ́,wọ́n sì kórìíra rẹ,tí kò sí ẹni tí ń gba ààrin rẹ̀ kọjá mọ́,n óo sọ ọ́ di àmúyangàn títí lae;àní, ohun ayọ̀ láti ìrandíran.

16. O óo mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè,o óo mu wàrà àwọn ọba.O óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni olùgbàlà rẹ,ati Olùràpadà rẹ, Ẹni Ńlá Jakọbu.

17. “Dípò bàbà, wúrà ni n óo mú wá.Dípò irin, fadaka ni n óo mú wá.Dípò igi, bàbà ni n óo mú wá.Dípò òkúta, irin ni n óo mú wá.N óo mú kí àwọn alabojuto yín wà ní alaafia,àwọn akóniṣiṣẹ́ yín yóo sì máa ṣe òdodo.

Aisaya 60