Aisaya 60:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dìde, tan ìmọ́lẹ̀; nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,ògo OLUWA sì ti tàn sára rẹ.

2. Nítorí òkùnkùn yóo bo ayé mọ́lẹ̀,òkùnkùn biribiri yóo sì bo àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ OLUWA yóo tàn sára rẹ,ògo OLUWA yóo sì hàn lára rẹ.

3. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ,àwọn ọba yóo sì wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ tí ń tàn.

4. Gbé ojú sókè kí o wò yíká,gbogbo wọn kó ara wọn jọ, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;àwọn ọmọ rẹ ọkunrin yóo wá láti òkèèrè,a óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin lé apá wá.

Aisaya 60