4. Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín,ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà.Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run.
5. Ṣé irú ààwẹ̀ tí mo yàn nìyí, ọjọ́ tí eniyan yóo rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lásán?Ṣé kí eniyan lè doríkodò bíi koríko etí odò nìkan ni?Tabi kí ó lè jókòó lórí aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú nìkan?Ṣé èyí ni ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀, ati ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA?
6. “Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé:kí á tú ìdè ìwà burúkú,kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà;kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́,kí á já gbogbo àjàgà?
7. Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín,bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó,kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín.