8. OLUWA ní,“Nítorí èrò tèmi yàtọ̀ sí tiyín,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi yàtọ̀ sí tiyín,
9. Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín,tí èrò mi sì ga ju èrò yín.
10. “Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run,tí wọn kì í pada sibẹ mọ́,ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀,tí ń mú kí nǹkan hù jáde;kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn,kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ.