9. Ẹ jọ máa kọrin pọ̀,gbogbo ilẹ̀ Jerusalẹmu tí a sọ di aṣálẹ̀,nítorí OLUWA yóo tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,yóo ra Jerusalẹmu pada.
10. OLUWA yóo lo agbára mímọ́ rẹ̀, lójú àwọn orílẹ̀-èdè,gbogbo eniyan, títí dé òpin ayé, yóo sì rí ìgbàlà Ọlọrun wa.
11. Ẹ jáde, ẹ jáde ẹ kúrò níbẹ̀,ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan,ẹ jáde kúrò láàrin rẹ̀, kí ẹ sì wẹ ara yín mọ́,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò OLUWA.
12. Nítorí pé ẹ kò ní fi ìkánjú jáde,bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní sáré jáde.Nítorí OLUWA yóo máa lọ níwájú yín,Ọlọrun Israẹli yóo sì wà lẹ́yìn yín.