Aisaya 50:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní:OLUWA ní:“Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí mo fi kọ àwọn eniyan mi sílẹ̀ dà?Ta ni mo tà yín fún,tí mo jẹ lówó?Ẹ wò ó! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ni a ṣe tà yín,nítorí àìdára yín ni mo ṣe kọ̀ yín sílẹ̀.

2. “Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan;mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn?Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni;àbí n kò lágbára láti gba ni là?Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun,tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀,omi wọn gbẹ,òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa,wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn.

Aisaya 50