Aisaya 43:10-19 BIBELI MIMỌ (BM)

10. OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn;kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́,kí ó sì ye yín pé, Èmi ni.A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi,òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi.

11. “Èmi ni OLUWA,kò sí olùgbàlà kan, yàtọ̀ sí mi.

12. Mo ti sọ̀rọ̀ ìṣípayá, mo ti gba eniyan là,mo sì ti kéde,nígbà tí kò sí Ọlọrun àjèjì láàrin yín;ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

13. Èmi ni Ọlọrun,láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi ni.Kò sí ẹnìkan tí ó lè gba eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ mi:Ta ni le dínà ohun tí mo bá níí ṣe?”

14. OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní,“N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín,n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè,ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún.

15. Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín,Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.”

16. OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun,tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá;

17. ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun;wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́,wọ́n kú bí iná fìtílà.

18. ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́,kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá.

19. Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titunó ti yọ jáde nisinsinyii,àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀?N óo la ọ̀nà ninu aginjù,n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.

Aisaya 43