3. Kò ní ṣẹ́ ọ̀pá ìyè tí ó tẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní pa iná fìtílà tí ń jò bẹ́lúbẹ́lú,yóo fi òtítọ́ dá ẹjọ́.
4. Kò ní kùnà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì,títí yóo fi fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ láyé.Àwọn erékùṣù ń retí òfin rẹ̀.”
5. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ;ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ,tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀;ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀;tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀.