Aisaya 35:9-10 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Kò ní sí kinniun níbẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ẹranko burúkú kankan kò ní gba ibẹ̀.A kò ní rí wọn níbẹ̀,àwọn tí a ti rà pada ni yóo gba ibẹ̀.

10. Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada,wọn óo wá sí Sioni pẹlu orin,ayọ̀ ayérayé yóo kún inú wọn.Wọn óo rí ayọ̀ ati ìdùnnú gbàìbànújẹ́ ati òṣé yóo sá kúrò níbẹ̀.

Aisaya 35