8. Nisinsinyii lọ kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú wọn,kí o sì kọ ọ́ sinu ìwé,kí ó lè wà títí di ẹ̀yìn ọ̀la,gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí lae;
9. nítorí aláìgbọràn eniyan ni wọ́n,Òpùrọ́ ọmọ tí kìí fẹ́ gbọ́ ìtọ́ni OLUWA.
10. Wọ́n á máa sọ fún àwọn aríran pé,“Ẹ má ríran mọ.”Wọ́n á sì máa sọ fún àwọn wolii pé,“Ẹ má sọ àsọtẹ́lẹ̀ òtítọ́ fún wa mọ́,ọ̀rọ̀ dídùn ni kí ẹ máa sọ fún wa,kí ẹ sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn fún wa.
11. Ẹ fi ojú ọ̀nà sílẹ̀, ẹ yà kúrò lójú ọ̀nà,ẹ má sọ nípa Ẹni Mímọ́ Israẹli fún wa mọ́.”
12. Nítorí náà, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:“Nítorí pé ẹ kẹ́gàn ọ̀rọ̀ yìí,ẹ gbẹ́kẹ̀lé ìninilára ati ẹ̀tàn,ẹ sì gbára lé wọn,
13. nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá yìí;yóo dàbí ògiri gíga tí ó là, tí ó sì fẹ́ wó;lójijì ni yóo wó lulẹ̀ lẹ́ẹ̀kanṣoṣo.