Aisaya 30:3-9 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Nítorí náà, ààbò Farao yóo di ìtìjú fún wọn,ibi ìpamọ́ abẹ́ Ijipti yóo di ìrẹ̀sílẹ̀ fún wọn.

4. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olórí wọn ti lọ sí Soani,tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé Hanesi.

5. Ojú yóo tì wọ́n, nítorí wọn ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kò lè ràn wọ́n lọ́wọ́.Wọn kò lè rí ìrànwọ́ tabi anfaani kankan níbẹ̀, bíkòṣe ìtìjú ati ẹ̀gàn.”

6. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Nẹgẹbu nìyí:“Wọ́n di àwọn nǹkan ìní wọn sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,wọ́n sì di ìṣúra wọn sí ẹ̀yìn ràkúnmí.Wọ́n ń la ilẹ̀ ìṣòro ati wahala kọjá.Ilẹ̀ àwọn akọ kinniun ati abo kinniun,ilẹ̀ paramọ́lẹ̀ ati ejò amúbíiná tí ń fò.Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan tí kò lè ṣe wọ́n ní anfaani.

7. Nítorí ìmúlẹ̀mófo ni ìrànwọ́ Ijipti.Nítorí náà ni mo ṣe pè é ní,‘Rahabu tí ń jókòó lásán.’ ”

8. Nisinsinyii lọ kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú wọn,kí o sì kọ ọ́ sinu ìwé,kí ó lè wà títí di ẹ̀yìn ọ̀la,gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí lae;

9. nítorí aláìgbọràn eniyan ni wọ́n,Òpùrọ́ ọmọ tí kìí fẹ́ gbọ́ ìtọ́ni OLUWA.

Aisaya 30