Aisaya 24:3-10 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ogun yóo kó ilé ayé,yóo di òfo patapata.Nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

4. Ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo nǹkan ń rọ.Ayé ń joró, ó sì ń ṣáàwọn ọ̀run ń joró pẹlu.

5. Àwọn tí ń gbé inú ayé ti ba ilé ayé jẹ́,nítorí pé wọ́n ti rú àwọn òfinwọ́n ti tàpá sí àwọn ìlànàwọ́n sì da majẹmu ayérayé.

6. Nítorí náà ègún ń pa ayé run lọ.Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,iná ń jó àwọn olùgbé inú rẹ̀,eniyan díẹ̀ ni ó sì kù.

7. Ọtí waini ń ṣọ̀fọ̀.Igi èso àjàrà ń joró,gbogbo àwọn tí ń ṣe àríyá ti ń kẹ́dùn.

8. Ìró ìlù ayọ̀ ti dákẹ́,ariwo àwọn alárìíyá ti dópin.Àwọn tí ń tẹ dùùrù ti dáwọ́ dúró.

9. Wọn kò mu ọtí níbi tí wọ́n ti ń kọrin mọ́ọtí líle sì korò lẹ́nu àwọn tí ń mu ún.

10. Ìlú ìdàrúdàpọ̀ ti wó palẹ̀, ó ti dòfo,gbogbo ìlẹ̀kùn ilé ti tì, kò sì sí ẹni tí ó lè wọlé.

Aisaya 24