14. OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi tó mi létí pé:“A kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì yíntítí tí ẹ óo fi kú.”
15. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní, “Lọ bá Ṣebina, iranṣẹ ọba, tí ó jẹ́ olórí ní ààfin ọba, Kí o bi í pé:
16. ‘Kí ni o fẹ́ máa ṣe níhìn-ín? Ta ni o sì ní níhìn-ín tí o fi gbẹ́ ibojì síhìn-ín fún ara rẹ? Ìwọ tí o gbẹ́ ibojì sórí òkè, tí o kọ́ ilé fún ara rẹ ninu àpáta?
17. Wò ó! OLUWA yóo fi tipátipá wọ́ ọ sọnù ìwọ alágbára. Yóo gbá ọ mú tipátipá.
18. Yóo fì ọ́ nàkànnàkàn, yóo sì sọ ọ́ nù bíi bọ́ọ̀lù, sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, níbẹ̀ ni óo kú sí. Níbẹ̀ ni àwọn kẹ̀kẹ́-ogun rẹ tí ó dára yóo wà, ìwọ tí ò ń kó ìtìjú bá ilé OLUWA rẹ.
19. N óo tì ọ́ kúrò ní ààyè rẹ, n óo fà ọ́ lulẹ̀ kúrò ní ipò rẹ.’