Aisaya 20:4-6 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria yóo ṣe kó àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Kuṣi lẹ́rú, ati ọmọde ati àgbàlagbà wọn, ní ìhòòhò, láì wọ bàtà. A óo bọ́ aṣọ kúrò lára wọn, kí ojú ó lè ti Ijipti.

5. Ìbẹ̀rù-bojo yóo dé ba yín, ojú yóo sì tì yín; nítorí Kuṣi ati Ijipti tí ẹ gbójú lé.

6. Àwọn tí ń gbé etí òkun ilẹ̀ yìí yóo wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ẹ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a gbójú lé, àwọn tí à ń sá tọ̀ lọ pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́, kí wọ́n gbà wá lọ́wọ́ ọba Asiria. Báwo ní àwa óo ṣe wá là báyìí?’ ”

Aisaya 20