Aisaya 2:7-13 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Wúrà ati fadaka kún ilẹ̀ wọn,ìṣúra wọn kò sì lópin.Ẹṣin kún ilẹ̀ wọn,kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lóǹkà.

8. Ilẹ̀ wọn kún fún oriṣa,wọ́n ń bọ iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,wọ́n ń wólẹ̀ fún ohun tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe.

9. Bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe tẹ ara rẹ̀ lórí batí ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.Oluwa, máṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.

10. Ẹ wọnú àpáta lọ,kí ẹ sì farapamọ́ sinu ilẹ̀.Ẹ sá fún ibinu OLUWAati ògo ọlá ńlá rẹ̀.

11. A óo rẹ ọlọ́kàn gíga eniyan sílẹ̀,a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀;OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà.

12. Nítorí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀,tí yóo dojú ìjà kọ àwọn agbéraga,ati àwọn ọlọ́kàn gíga,ati gbogbo nǹkan tí à ń gbéga.

13. Yóo dojú kọ gbogbo igi Kedari ti Lẹbanoni,tí ó ga fíofío, ati gbogbo igi oaku ilẹ̀ Baṣani;

Aisaya 2