1. O óo sọ ní ọjọ́ náà pé,“N óo fi ọpẹ́ fún OLUWA,nítorí pé bí ó tilẹ̀ bínú sí mi,inú rẹ̀ ti rọ̀, ó sì tù mí ninu.
2. Wò ó! Ọlọrun ni olùgbàlà mi,n óo gbẹ́kẹ̀lé eẹ̀rù kò sì ní bà mí,nítorí pé OLUWA Ọlọrun ni agbára mi, ati orin mi,òun sì ni Olùgbàlà mi.”
3. Tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa rí ìgbàlàbí ẹni pọn omi láti inú kànga.