Sekaráyà 8:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá, wí pé,

2. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Owú ńlá-ńlá ni mo jẹ fún Síónì, pẹ̀lú ìbínú ńlá-ńlá ni mo fi jowú fún un.”

3. Báyìí ni Olúwa wí: “Mo yípadà sí Síónì èmi ó sì gbé àárin Jérúsálẹ́mù: Nígbà náà ni a ó sì pé Jérúsálẹ́mù ni ìlú ńlá otítọ́; àti òkè-ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè-ńlá mímọ́.”

Sekaráyà 8