Sekaráyà 5:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsí i, obìnrin méjì jáde wá, èfúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn; nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀: Wọ́n sì gbé òṣùwọ̀n éfà náà dé àárin méjì ayé àti ọ̀run.

10. Mo sì sọ fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òṣùwọ̀n éfà náà lọ.”

11. Ó si wí fún mi pé, “Sí orílẹ̀ èdè Bábílónì láti kọ ilé fún un. Tí ó bá ṣe tán, a ó sì fi ìdí rẹ̀ mulẹ̀, a o sì fi ka orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.”

Sekaráyà 5