Sekaráyà 5:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì jáde lọ, ó sì wí fún mi pé, “Gbé ojú rẹ sókè níṣinṣin yìí, kí o sì wo nǹkan yìí tí ó jáde lọ.”

6. Mo sì wí pé, “Kí ni nǹkan náà?”Ó sì wí pé, “Èyí ni òṣùwọ̀n éfà tí ó jáde lọ.” Ó sì wí pé, “Èyí ni àwòrán ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”

7. Sì kíyèsí i, a gbé talẹ́ńtì òjé sókè: obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárin òṣùwọ̀n éfà.

8. Ó sì wí pé, “Èyí ni ìwà-búburú.” Ó sì jù ú sí àárin òṣùwọ̀n éfà: ó sì ju òṣùwọ̀n òjé sí ẹnu rẹ̀.

Sekaráyà 5