Sekaráyà 1:14-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ańgẹ́lì ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbé wí pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jówú fún Jérúsálẹ́mù àti fún Síónì.

15. Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí o gbé jẹ́ẹ: nítorí nígbà ti mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀ṣíwájú.’

16. “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jérúsálẹ́mù wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jérúsálẹ́mù.’

17. “Má a ké síbẹ̀ pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘A o máa fi ire kun ilú-ńlà mi ṣíbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Síónì nínú ṣíbẹ̀, yóò sì yan Jérúsálẹ́mù ṣíbẹ̀.’ ”

18. Mo si gbé oju sòkè, mo sì rí, sì kíyèsí i, ìwo mẹ́rin.

19. Mo sì sọ fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?”Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Júdà, Ísírélì, àti Jérúsálẹ́mù ká.”

Sekaráyà 1