1. Olúwa jọba;jẹ́ kí ayé kí ó wárìrìo jòkòó lórí ìtẹ́ kérúbùjẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
2. Olúwa tóbi ní Síónì;o sì ga jù gbogbo orílẹ̀ èdè lọ.
3. Kí wọ́n sì yín orúkọ Rẹ̀ tí ó tóbití ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun.
4. Olúwa tóbi lọba, ó fẹ́ òdodo ó dá ìdọ́gba sílẹ̀;ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí o yẹ nínú Jákọ́bù.
5. Gbígbé ga ní Olúwa Ọlọ́run waẹ foríbalẹ̀ níbi ẹṣẹ̀ Rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.
6. Mósè àti Árónì wà nínú àwọn àlùfáà Rẹ̀Sámúẹ́lì wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ Rẹ̀wọ́n képe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.