Sáàmù 96:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.

2. Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ Rẹ̀ẹ sọ ti ìgbàlà Rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́

3. Ẹ sọ ti ògo Rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdèàti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ láàrin gbogbo ènìyàn.

4. Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ sí;òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìsà lọ

5. Nítorí aṣán ni gbogbo àwọn òrìsà orílẹ̀ èdèṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run

6. Ọlá àti ọlá ńlá wà ni ìwájú Rẹ̀agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ Rẹ̀.

7. Ẹ fi fún Olúwa, ẹ yin ìbátan ènìyànẸ fi agbára àti ògo fún Olúwa

Sáàmù 96