Sáàmù 96:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.

2. Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ Rẹ̀ẹ sọ ti ìgbàlà Rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́

3. Ẹ sọ ti ògo Rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdèàti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ láàrin gbogbo ènìyàn.

Sáàmù 96