Sáàmù 95:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí OlúwaẸ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.

2. Ẹ jẹ́ kí a wá sí ìwájú Rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́kí a sì pòkìkí Rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlòorin àti ìyìn.

3. Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.

4. Ní ọwọ́ Rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.

5. Tirẹ̀ ni òkun, nítorí òun ni ó dá aàti ọwọ́ Rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

Sáàmù 95