Sáàmù 94:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;Ọlọ́run Jákọ́bù kò sì kíyèsí i.”

8. Kíyèsí i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyànẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?

9. Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bi?Ẹni tí ó dá ojú?Ó ha lè ṣe láìríran bi?

10. Ẹni tí ń bá orílẹ̀ èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni sọ́nà bí?Ẹni ti ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?

Sáàmù 94