Sáàmù 94:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.

14. Nítorí Olúwa kò ní kọ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀;Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní Rẹ̀ sílẹ̀.

15. Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,àti gbogbo àwọn ọlọ́kàndídúró ṣinṣin yóò tẹ̀ lé e lẹ́yìn.

16. Ta ni yóò dìde fún misí àwọn olùṣe búburú?Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?

17. Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,èmi fẹ́rẹ̀ má a gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́

Sáàmù 94