Sáàmù 89:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Òdodo àti òtítọ́ ní ìpílẹ̀ ìtẹ́ Rẹ:ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ ṣíwájú Rẹ.

15. Ìbùkún ní fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ igbe ayọ̀,tí ó ń rìn Olúwa nínú ìmọ́lẹ̀ oju Rẹ.

16. Wọn ń ṣògo nínú orúkọ Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,wọn ń yin òdodo Rẹ.

17. Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;nípa ojúrere ni ìwọ wá ń ṣògo.

18. Nítorí tí Olúwa ni asà wa,ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

19. Nígbà náà ní ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran sí àwọn olótítọ́ Rẹ, wí pé:“èmi tí gbé adé kálẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,èmi ti gbé ẹni tí a yan láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.

20. Èmi tí rí Dáfídì ìránṣẹ́ mi;pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ní mo fi yàn án;

21. Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú Rẹ̀a pá mí yóò sì fi agbára fún un.

Sáàmù 89