Sáàmù 86:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí ìwọ, Olúwa,ní mo gbé ọkan mí sókè sí.

5. Ìwọ ń daríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn ti ń ké pè ọ́,

6. Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;tẹ́tí sí ẹkún fún àánú.

7. Ní ọjọ́ ipọ́njú mi èmi yóò pe ọ́,nítorí ìwọ yóò dá mí lóhùn.

8. Nínú àwọn òrìṣà kò sì ẹni tí ó dà bí Rẹ, Olúwa:kò sí àwọn iṣẹ́ tí a le fi wé tìrẹ.

9. Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ dáyóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú Rẹ, Olúwa;wọn o mú ògo wà fún orúkọ Rẹ̀.

10. Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ si ń ṣe ohun ìyanu;ìwọ nìkan ní Ọlọ́run.

11. Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, Olúwa,èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ Rẹ;fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ Rẹ.

Sáàmù 86