Sáàmù 78:31-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọnó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ísírẹ́lì bolẹ̀.

32. Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọn ń sá síwájú;nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́

33. O fi òpin sí ayé wọn nínú asánàti ọdún wọn nínú ìpayà.

34. Nígbà kígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,wọn yóò wá a kirì;wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.

35. Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;wí pé Ọlọ́run ọ̀gá ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn

36. Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n-ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́nwọ́n fí ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;

37. Ọkàn wọn kò sòtítọ́ si i,wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú Rẹ̀.

38. Ṣíbẹ̀ ó ṣàánú;ó dárí àìṣedédé wọn jìnòun kò sì pa wọn runnígbà kí ì gbà ló ń dá ìbínú Rẹ̀ dúrókò sì rú ìbínú Rẹ̀ sókè

39. Ó ránti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò le padà.

40. Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ síi ní ihàwọn mú-un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!

41. Síwájú àti síwájú wọn dán Ọlọ́run wò;wọ́n mú ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì bínú.

42. Wọ́n kò rántí agbára Rẹ̀:ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,

43. Ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ hàn ní Éjíbítì,àti iṣẹ́ àmì Rẹ ni ẹkùn Sáónì

44. Ó ṣọ omi wọn dí ẹ̀jẹ̀;wọn kò le mú láti odò wọn.

45. Ó rán ọ̀wọ́ ẹṣinṣin láti pa wọ́n run,àti ọpọlọ tí ó bá wọn jẹun.

Sáàmù 78