Sáàmù 78:29-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Wọn jẹ, wọ́n sí yó jọjọnítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún

30. Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọ́n fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,

31. Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọnó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ísírẹ́lì bolẹ̀.

32. Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọn ń sá síwájú;nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́

33. O fi òpin sí ayé wọn nínú asánàti ọdún wọn nínú ìpayà.

Sáàmù 78