Sáàmù 75:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdajọ́;Òun Rẹ̀ ẹnìkan sílẹ̀, ó sí ń gbé ẹlòmíràn ga.

8. Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,ọtí wáìnì náà sì pọ́n,ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pòpọ̀ mọ́ òórùn dídùntí ó tú jáde, àti búburú ayé gbogbomú u sílẹ̀ pátapáta.

9. Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn Rẹ títí láé;Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jákọ́bù (Ísírẹ́lì)

10. Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.

Sáàmù 75