1. Olúwa, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú Rẹkí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú Rẹ
2. Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń ku lọ; Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
3. Ọkàn mi wà nínú ìrora.Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?
4. Yípadà, Olúwa, kí ó sì gbà mí;gbà mí là nípa ìfẹ́ Rẹ tí kì í ṣákìí.
5. Ẹnikẹ́ni kò sì rántí Rẹ nígbà tí ó bá kú.Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú iṣà òkú?
6. Agara ìkérora mi da mi tán;gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkúnmo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
7. Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.