Sáàmù 32:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìbùkún ni fún àwọntí a dárí ìrékọjá wọn jìn,tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

2. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náàẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ sí i lọ́rùnàti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

3. Nígbà tí mo dákẹ́,egungun mi di gbígbó dànùnípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.

4. Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òruọwọ́ Rẹ̀ wúwo sími lára;agbára mi gbẹ tángẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn Sela

Sáàmù 32