Sáàmù 27:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Gbọ́ ohùn mi nígbà tẹ́mi báà ń pè, Áà Olúwa,ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;

8. “Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u Rẹ̀”Ojú ù Rẹ, Olúwa, ni èmí ń wá,

9. Má ṣe fi ojú Rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,má ṣe fi ìbínú ṣá ìránṣẹ́ Rẹ tì;ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,Má ṣe ju mi sílẹ̀, má si ṣe kọ̀ mí,áà Ọlọ́run ìgbàlà mi.

10. Bí ìyá àti bàbá bá kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.

11. Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, Olúwa,kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́júnítorí àwọn ọ̀tá mi.

12. Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀ta mi lọ́wọ́,nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,wọ́n sì mí ìmí ìkà.

13. Èmi ní ìgbàgbọ́ péèmi yóò rí ìre Olúwaní ilẹ̀ alààyè.

14. Dúró de Olúwa;kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn leàní dúró de Olúwa.

Sáàmù 27