27. Gbogbo òpin ayé ni yóò rántíwọn yóò sì yípadà sí Olúwa,àti gbogbo ìdílé orílẹ̀ èdèni wọn yóò jọ́sìn níwájú Rẹ̀,
28. Nítorí ìjọba ni ti Olúwa.Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀ èdè.
29. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àṣè, wọn yóò sì sìn;gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájúu Rẹ̀àti ẹni ti kò le pa ọkàn ara Rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
30. Irú ọmọ Rẹ̀ yóò sìn-in;a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ nípa Olúwa,
31. Wọn yóò polongo òdodo Rẹ̀sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,wí pé òun ni ó ṣe èyí.