Sáàmù 18:20-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi

21. Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́;èmi kò ṣe búbúrú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi

22. Gbogbo òfin Rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà Rẹ̀.

23. Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Rẹ̀;mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.

24. Olúwa san ẹ̀ṣan fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú Rẹ̀.

25. Sí olóòótọ́ ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní olóòtọ́,sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,

26. Sí ọlọ́kan mímọ́, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní òǹrorò.

27. O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n o Rẹ̀ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.

Sáàmù 18