Sáàmù 147:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Olúwa ní ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú Rẹ̀.

12. Yin Olúwa, ìwọ Jérúsálẹ́mùyin Ọlọ́run Rẹ̀, ìwọ Síónì.

13. Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ìbodè Rẹ̀ lágbára;Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ Rẹ̀ nínú Rẹ

14. Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè Rẹ̀òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.

15. Òun sì rán àṣẹ Rẹ̀ sí ayéọ̀rọ̀ Rẹ̀ sáré tete.

16. Ó fi sino fún ni bi irun àgùntànó sì fọ́n ìrì idídì ká bí eérú

Sáàmù 147