Sáàmù 142:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi kígbe sókè sí Olúwa;Èmi gbé ohùn mi sókèsí Olúwa fún àánú.

2. Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú Rẹ̀bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú Rẹ̀.

3. Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣààrẹ̀ nínú mi,ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìnènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀

4. Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì wò ókò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn fún mièmi kò ní ààbò;kòsí ẹni tí ó ṣe àníyàn fún ayé mi.

5. Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:èmi wí pe, “ìwọ ni ààbò mi,ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè”

6. Fi etí sí igbe mi, nítorí tí èmiwà nínú àníìrètígbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,nítorí wọ́n lágbára jù mi lọ

Sáàmù 142