Sáàmù 119:148-158 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

148. Ojú mi ṣááju ìsọ́ òru,nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ r.

149. Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ:pa ayé mí mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

150. Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòòsí,ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin Rẹ.

151. Ṣíbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,àti gbogbo àsẹ Rẹ jẹ́ òtítọ́.

152. Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin Rẹtí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.

153. Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,nítorí èmi kò gbàgbé òfin Rẹ.

154. Gba ẹjọ́ mi rò kí ó sì rà mí padà;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

155. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburúnítorí wọn kò wá àṣẹ Rẹ.

156. Ìyọ́nú Rẹ̀ tóbi, Olúwa;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

157. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀ta tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,ṣùgbọ́n èmi kò tíì yí padà kúrò nínú òfin Rẹ.

158. Èmi wọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ Rẹ gbọ́.

Sáàmù 119