Sáàmù 119:135-141 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

135. Jẹ́ kí ojú Rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ Rẹ lárakí ó sì kọ́ mi ní àsẹ Rẹ.

136. Omijé sàn jáde ní ojú mi,nítorí wọn kò gba òfin Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.

137. Olódodo ni ìwọ Olúwaìdájọ́ rẹ sì dúró sinsin

138. Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.

139. Ìtara mi ti pami run,nítorí àwọn ọ̀ta mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ Rẹ dá.

140. Wọ́n ti dán ìpinnu Rẹ wò pátapátaìránṣẹ́ Rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.

141. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gànèmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ Rẹ.

Sáàmù 119