1. Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́sẹ̀,ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa,
2. Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin Rẹ̀ mọ́tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
3. Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;wọ́n rìn ní ọ̀nà Rẹ̀.
4. Ìwọ ti la ìlànà Rẹ̀ sílẹ̀kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
5. Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣinláti máa pa òfin Rẹ̀ mọ́!