5. Nínú ìrora mi, mo sunkún sí Olúwa,ó sì dámi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.
6. Olúwa, ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.Kí ni ènìyàn lè ṣe si mi?
7. Olúwa n bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ miNítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìfẹ́ mi lórí àwọn ti ó kórìíra mi.
8. Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwaju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.
9. Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwaju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ aládé lọ.
10. Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè yí mi káàkiri,ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò