Sáàmù 118:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

2. Jẹ́ kí Ísírẹ́lì wí pé:“Àánú Rẹ̀ dúró láéláé”.

3. Jẹ́ kí ilé Árónì wí pé:“Àánú Rẹ̀ dúró láéláé”.

4. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé:“Àánú Rẹ̀ dúró láéláé.”

5. Nínú ìrora mi, mo sunkún sí Olúwa,ó sì dámi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.

6. Olúwa, ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.Kí ni ènìyàn lè ṣe si mi?

Sáàmù 118