Sáàmù 107:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ìyanu Rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,

9. Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́runó sì fi ire fún ọkàn tí ebi ń pa.

10. Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,a dè wọ́n ni ìrora àti ní irin,

11. Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀Ọlọ́run, wọn kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá ògo,

12. Ó sì fi ìkorò Rẹ àyà wọn sílẹ̀;wọn ṣubú, kò sì sí ẹni tíyóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

13. Ní ìgbà náà wọ́n ké pe Olúwa nínú ìdàámú wọn,ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn

14. Ó mú wọn jáde kúrò nínúòkùnkùn àti òjìji ikú,ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.

15. Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa Nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.

16. Nítorí tí ó já ilẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nìó sì ke irin wọ̀n nì ní agbede-méjì.

17. Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọnwọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn

Sáàmù 107