Sáàmù 107:39-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù

40. Ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ aládéó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí

41. Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìniraó mú ìdílé wọn pọ̀ bi agbo ẹran

42. Àwọn tí ó dúró sì ríi, inú wọn sì dùnṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu Rẹ̀ mọ́.

43. Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsí nǹkan wọ̀nyíkí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.

Sáàmù 107